EWÍ — OMINIRA
Mebí wónni títa ríro laa kolà,bóbá jiná tán a doge
Ojú kìípósin kómá là ni àwon àgbà únwí
Emi lówá dé tómìnira sewá doun ègàn nílèyí
Òmìnira oun Omi ìnira kòwá yátò síra won ní naija únbí
Terú tomo niwón ún kígbe ólekoko
Omo eléran wá n jegun,aláso n wo àkísà
Àbámò wá gbenu terú tomo kan
Omase ooo, ayeye oríleèdè lé lódún làa ñ se nílè yí lódodún, be eku òké bí eku,Omo èyàn oti foún bí èyàn
Aatíi gbó pé Omo tólé lógóta odún kò kúrò nípò rírá bi Omo tuntun
Aatíi gbó pé Omo olówó n toro oúnje je ni
Èyin olórí nílèyí ,èyin ni mo bá léjó ,ebá wa tún lèyí se èbè labè ,ejè ajáwó nínú àpòn tí ò yò ká ya gbómi ilá kaná,eeyé paró yio da fúnwa
Ojó wo gan nilèyí fé tèsíwájú ? eje n gbó
Towon ó dòpò ní salaria tiwa
Teerin ágbenu mùtúmùwà kan
Térú wa á domo
Èetirí!! Èetijé !!?
Eeyé fara niwá món
Oba òkè ti fúnwa lóun àlúmooni tó yeewa,ósewá jépé,ara wa laafi n nilara
Epo won gógó,aféfé gaasi òosé kolù loja
Naira owó ilè yí wá di pónkan lágbayé ejé áronú ká pínwà dà
Ominú komí pé ,ùnjé oun rere kan a ti lè ti Jerusalem naija jáde wá món?
Èyin àgbà e dákun ebá mi fèsì sórò tógbàpérò
Àfí kélédùà óbáwa dási kótó burú jai
Mojísé Orí ránmi, àbò lódààà
Gbogbo ẹtọ wa ni ipamọ. O ko ni ẹtọ lati tun tabi ṣe atẹjade eyikeyi akoonu lati oju opo wẹẹbu yii laisi igbanilaaye kikọ lati ọdọ NEB.
No comments