• Àwọn Ikó Agbábọọlu Com Science Da Gaari OTM Sínu Yeepẹ Pẹlu Ami Ayo Kan Sodo 1-0 Ninu Idije Ife Diini

     


    Akoroyin: Omololú Àjàyí 

    Òde o fararọ fun awọn akẹẹkọ nipa imọ ọfiisi (OTM) ti ile è̩kó̩ gbogbonise ilu iree loni ọjọ aje, o̩jó̩ kejilelogun osù ke̩san o̩dún 2025 ni papa isere Pavilion ti ile ẹkọ naa nigba ti wọn wọnko pẹlu awọn aké̩ké̩ nipa ìmò̩ e̩ro̩ aye ode oni (Computer science) ti o ọrọ si pada bẹyin yọ fun awọn akẹkọ nipa imọ ọfiisi nigba ti awọn akẹkọ nipa imọ ẹrọ aye ode oni bu ifọti luwọn pẹlu ami ayokan sodo


    Nibi idije ọhun lọpọ ololufẹ ere idaraya bọọlu alafẹsẹgba lati igun mejeeji pejusi loni láti wá sàtile̩yin fún awọn eniyan wọn, nigbati ẹka ikọwe mejeeji wọnko pẹlu ara wọn 


    Ninu ìfò̩rò̩werọ pè̩lu awọn akọroyin Nẹẹbu, Aarẹ lẹka imọ ọfiisi, Comerade Abiodun Omotosho to tun jẹ ọkan lara awọn agbabọọlu ọhun fi aidunnu rè̩ han, to si sàlayé idije naa gé̩gé̩ bi oun to ba ohun lọkan jẹ pè̩lu latari bose jé̩ idije to gbè̩yin fun ohun gé̩gé̩ bi aké̩kó̩ ninu o̩gba ile è̩kó̩ naa, to si salayepe aisi ibasepọ to danmọra laarin awọn agbabó̩ọ̀lu naa lofa ijakulè̩


    Bakannaa, Comerade Oshagbemi Ebenezer ti ò̩pò̩ mọ̀si 'Eben' ti ikọ to gbegba oroke se lalaye wipe isọkan ati ipinnu lo se atilẹyin láti le gbegba oroke naa, ko se alai fikun ọrọ rẹ pe "ò̩pò̩ eniyan lo ti ro awọn pin wipe awọn o le pagọ, sùgbó̩n tí àwọn se bé̩è̩ kó̩lé̩ alarinrin,O tun sàlàye idije naa bi eleyi to le ju ninu idije awon sugọn ti awọn bori pẹlu ìfarajin, isọkan ati igbafunraẹni" Osogbemi lo sọ bẹẹ


    Nigbẹyin, Eesi tọka awọn asoju akẹkọ nípa imọ è̩ro̩ aye ode oni (Com Science) ninu idije naa gẹgẹ bi agbabọọlu to ta lẹnu julọ ninu idije naa.

    Gbogbo ẹtọ wa ni ipamọ. O ko ni ẹtọ lati tun tabi ṣe atẹjade eyikeyi akoonu lati oju opo wẹẹbu yii laisi igbanilaaye kikọ lati ọdọ NEB. 

    Kan si Olootu;@NAMACOSONLINE

    1 comment: