• Popular Lulè̩ Ninu Abajade Èèsì Ìbò NAMACOS, Ojú Bó

     


    Akoroyin: Omololú Àjàyí 

    Èkọ o soju mimu fun awo̩n ikò̩ oloselu popular ninu eto ìdìbo awọn aké̩kọ e̩ka ìroyin àti igbohunsafẹfẹ eleyi to wale lana ọjọ e̩ti o̩jó̩ kẹtadinlogun osu ke̩wa o̩dun 2025 ti a wa yi, leyi ti ibo naa lọ nirọwọ rọsẹ ti ko mu wahala kankan dani botiwu komọ ti gbogbo oludibo si jẹ ọọdunrun din mẹjọ niye (292)


    Gé̩gé̩ bi awo̩n ajọ eleto idibo naa se so̩, ọgọrun din mẹta akẹkọ (97) lo dibo lati ipele alakọbẹrẹ ND1 ati ND2 ti àwọn aké̩kọ igbadinmarun (195) si dibo lati ipele HND1 ati HND2


    Ninu idibo sipo aarẹ ẹgbẹ aké̩ko̩ ni ajo̩ eleto idibo akẹkọ (ISEC) ti kéde Kazeem ge̩gé̩ bi e̩ni to jé̩we olubori lé̩yin to fe̩yin ake̩gbé̩ rè̩ janlè̩ pe̩lu ibo mé̩talelọgọjọ (163 votes) ti akẹgbẹ rè̩ Popular si ri ibo mọkandinlọgọfa (119 votes) leyi ti won si yọ ibo mẹwa danu latari ai kunju osunwọn ti won gbekalẹ


    Labala oluse ayẹwo iwe owo (Auditor) Famakinde Michael Temidayo (Parma) bori pè̩lú ibo mẹtalelogoje (143 votes) leyi to fi da oju Oyegbile Jamiu Yetunde tori ibo mejidinlọgọfa (118 votes) bolè̩


    Nigbonu alakoso yara ikawe (Liberian post) Abdulrafiu Yetunde Sukurat (Ope) jawe olubori pè̩lu ibo ogoje leyi ti alatako re̩ Adebisi Taiwo Lateef ti ọpọ mọ si (Classic) ri ibo mẹsandinlọgọrun 


    Labala alakoso igbayegbadun awọn aké̩ko̩ ( Welfare director) Alarape Shukurat Olabisi (Ashabi) ké̩sẹjari lẹyin to fidi alatako rè̩ janlè̩ pè̩lu ibo mọkandinlogoje ti alatako rẹ Opeyẹmi ri ibo mọkanlelọgọrun (91 votes)


    Awọn igbọngun ti ko ni alatako


    Oluseeto owo (Treasurer) Ganiyu Kaosarat Temiloluwa (Slimzy)

    Alamojuto owo (Financial Secretary) Olanitori Omolola Mary (Lady Khim)

    Oludari eeto awujo director) Olabamiji Ayomide Oluwafemi

    Adari ere idaraya (Sport Director) Olabamiji Ayomide Oluwafemi

    Igbakeji aare̩ (Oluronbi Lateef (Ola))

    Ako̩we apapọ (General Secretary) Oladele Iyiola Israel (Pastorate)

    Igbakeji akọwe apapọ (Assistant General secretary)Oladele Iyiola Israel (Pastorate)

    Alukoro ( Public relation officer) Asaye Blessing Adebukola (Vikky)


    Ninu ifọrọ wanilẹnuwo pè̩lu Aare̩ tuntun tawọn aké̩kó̩ dibo yan, Kazeem Adebayo dupé̩ lọwọ ọlọrun ati awọn akẹkọ to jade lati dibo fun to si se seleri wipe ki awon aké̩kọ o mọ reti nkan ò̩tun eleyi ti ohun seleri


    Aare̩ ti aké̩ko̩ diboyan wa se lalaye wipe oriire naa kiise ti ohun nikan bi ko se wipe ti gbogbo akẹkọ nipa isẹ iroyin ati igbohunsafẹfẹ to gbagbọ nipa ilọsiwaju ati isọkan, to si fi kun ọrọ rẹ wipe bi wọn ba gẹsin ninu ohun wipe kole kọsẹ rara lasikoyi o, o si sadehun lati gbe isejọba gidi kalẹ to fi mọ sise daada laarin awọn akẹkọ pẹlu


    Eeto idibo naa ni wọn sapejuwe gẹgẹ bi eyi to fẹẹ daraju ninu eto idibo ile ẹkọ naa latari lilọ nirọwọ rọsẹ ati eeto topeye pẹlu


    Lara awọn lọgalọga to wa nikalẹ nibi eeto idbo naa lati ri daju pe o lọ nirọwọ rọsẹ naa ni, Omowe Adeagbo ekeyi to soju awọn akasẹ ile ẹkọ lẹka igbayegbadun awọn akẹkọ ati awọn eleto abo to sisẹ papọ pẹlu awọn eleto idibo lati ri aridaju lilọ ni irọwọrọsẹ eeto idibo naa.

    Gbogbo ẹtọ wa ni ipamọ. O ko ni ẹtọ lati tun tabi ṣe atẹjade eyikeyi akoonu lati oju opo wẹẹbu yii laisi igbanilaaye kikọ lati ọdọ NEB. 

    Kan si Olootu;@NAMACOSONLINE

    No comments