ÌWÒYE ÌMỌ̀ LÁÀRÍÍN OLÙMỌ̀【Ewì tó yàtọ̀ sí fárá ń fàtàfátá】
Mo sùn, mo wá tògbẹ́ ìmọ̀ lọ kánrin, mo jí sínú ewì ìmọ̀.
Mo ta gìrì gìrì gìrì láti múra àlàáfíà, mo wá sè ìrìnàjò lọ sí ilé òye; àbájáde mi rèe, mo fẹ́ fi ṣe ọmọ aráyé lóore.
Mo pọn omi ìbà fún Ọba ìmọ̀, mo kí àwọn onímímọ̀ ní àgbáyé. Ewì ìkìlọ̀, ọgbọ́n, òye, ìṣítí gùn mí; òrò kì í gba àárọ̀, ká fi alẹ́ sọ ọ́, àsìkò àti kìlọ̀ ìwà ti tó, ìrírí àgbà ń'ṣe atọ́kùn fún ìkìlọ̀ ìwà.
Akẹ́kọ̀! Ẹwá wẹ̀ nínú odò ìmọ̀ pẹ̀lúù mi. Ẹ wá tògbé ìmọ̀ pẹ̀lúù mi. Òke yín rán yín ní ṣẹ́ ẹ̀kọ́; òbí ní kí wọ́n pọn omi òye wálé. Kíní ó ṣe yín tí è ń dágunlá? Ẹ ti gbàgbé pé ẹnití kò ní jẹ̀gbẹ̀jẹ̀gbẹ̀ lápá, kìí bá wọn dásà mokí ọ mokí ọ. Ẹnití kòní ògun arindọ̀, kìí báwọn je aáyán.
Ọ̀rẹ́ mi àtàtà! Má se fọ́ bíi igbá, bẹ́ẹ̀ni, máse là bí àwo táńgaran.
Ẹ̀kọ́ è rẹ ni kíó jẹ ó lógún ní ilé ẹ̀kọ́, rántí wípé omi tó bá mọ níwọ̀n, làhún rẹ́ ilá sí. Ìdúró ò sí, ìbẹ̀rẹ̀ ò sí fún ẹnití ó gbé odó mì. Ka ìwé rẹ, kí osì máa bẹ Olùbánisé kó bá ẹ ṣe tìrẹ.
Ẹ bámi kìlọ̀ fún alágbára kóyé jà kiri. Ṣé ó lè da omi àgbọn nù láìfọ́? Má ṣe fi ọwọ́ ẹni gbáni létí. Ṣe ọ̀ré aṣọ funfun, nífẹ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́. Ọnà àti parí èkuru nikí owá, má se báwọn gbọnwọ́ èkuru sí àwo. Sọ fún atóbitán kó ṣe jẹ́jẹ́. Ayé gba jẹ́jẹ́, ayé gba pẹ̀lẹ́, ayé gba ẹ̀rọ̀ pẹ̀sẹ̀.
Ẹ bá mi sọ fún àwọn tí wọ́ní àwọn làwọ́n lòní pé àwọn kọ́ ló lọ̀la. Ẹ bá mi kì lọ̀ fún gbégbé kó máa gbé ibi tóhún gbé; kó má baà té! Ẹ bá mi kìlọ̀ fún ọ̀lẹ afàjọ̀, olókuàdá; afasẹ́ gbe òjò ń (kàn) tan ara rẹ̀ jẹ ni. Ọmọ ìyá à mi! Gbọ́ ìkìlọ̀ kí òkété mọ́ baà bórù. Máṣe b'áwọn fi ọmọrí igbá kan bọ̀kan nínú; Ìgbà ń bọ̀ wá dára!
Bí a ríni lóde abèèrè, bí à ríni lóde abèèrè. Ìyọ́nú Ọlọ́hun, Àyànfẹ́ Olódùmarè kìí sahun ìmọ̀. Nítorí eyín ni Ọlọ́hun fí jíki ẹnu, miò tèta kìí sẹlẹ̀ ní ọ̀dẹ jagunjagun. Bí ògùn se máhún gu ni, tí sì ń lani lóògún, tí ń bí ogun kógun; bẹ́ẹ̀ni! Ìmọ̀, náà a máa lani ní òógùn. Bí èyàn bá rin ojú ọ̀nà ìtàkángbọ̀n ìmọ̀; yóò làágùn. Sùgbọ́n, Ọlọ́hun lótó gbẹ́kẹ̀lé.
Ìgi ìwé! Sóra fún ìyìn àyìnjù; kí o mọ́n baà di èso òdo. Rántí wípé ǹkan a máa ju ǹkan lọ. Bí iná bá rí omi tí ń dẹ́rù ba omi, yógbàgbá ilé tó fẹ́ jó. Baṣọ̀run gáà afi fìlà perin,
ọjọ́ kan ní ní yí mọn. Àpọ̀npa éégún ìgbómìnà, èté ní ídà. Ẹse rere, kí e lè gba ire.
Àwọn tí wọ́n máhún fi ẹnu kọ, wọ́n wó sùnsùn, wọ́n fi ẹsẹ̀ sílẹ̀, wọ́n wá ń fi ẹnu kọ. Kí ṣòrọ̀sọ̀rọ̀ ráńtí sọ́rọ̀sọ́rọ̀, gbogbo wa ni aní ẹlédàá ti wa. Afẹ́fẹ́ yagi oko, oko palọ́lọ́lọ́. E kìlọ̀ fún gbégbé kí ó máa gbé ibi tí ń gbé; kó má baà té!
'Misita' gbogbo igi mo lè gùn, oó padà gun igi aládi. Bí èyàn (tàbí ọ̀bọ rẹ) bá sáré gun igi ògẹ̀dẹ̀; yíò kan ìdin nínú iyọ̀. Hmmm, 'àntí' olósó, gbogbo ntí Ọlọ́hun fún yín, ni ekó síta, tí ẹ̀ẹ́ yan ara yín bẹ́ení yan ẹran. Àbí 'surname' yín ni oníranù? Sé 'nickname' yín ni oníṣekúṣe? Ẹyá a lọ jáwọ́!
Ọ̀rẹ́èmi ọ̀wọ́n, sọ́ra yan ọ̀ré! Ènìyàn dọ̀bálè, inúurẹ̀ lóso, bí iwájú ni wọ́n jó lọni ẹnìkan kòmò, bí ẹ̀yìn ni, ẹnìkan kòmò. Eré e kíni ajá ń bá ekùn se? Ódájú wípé eré ikú ni. Bíkú ilé ò sì pa'ni, tòde ò le pani!
Ọ̀rẹ́ẹ̀mi! Ṣebí ìwọ ni ọ̀réèmi? Gbà mí ní ìyànjú dáradára. Ìpàkọ́ onípàkọ́ ni à á rí, ẹni ẹlẹ́ni ní bá ni rí tẹni.
Mo tún ti dé ilé àwọn ẹgbẹ́ ẹlẹ́nu méjì. Èsù kékéke ni irú wọn. Wọ́n ní wọ́n pé ni baba irọ́. Tàbí ṣùgbọ́n ní ègbọ́n rè. Ó sojúù mi kòró ni bàbá ọ̀rọ̀ gan!
Ẹ máṣe bu ẹnu àtẹ́ lu olùkọ́; ẹni iyì, ẹni ẹ̀yẹ, ẹni àpónlé niwọ́n. Kí olùkọ́ náà wùwà bíi olùkọ́. Àbí èwo ni kí á máa fi ìdí gba máákì? Àbí èwo ni kí á tún máa san owó kí á tó 'páásì'? Ẹ̀yin nu Ọ̀lọ́hun nìyẹ!
Ẹ̀yin akéko tí e máhún gba 'máákì' gidi, Ẹ yá lọ sọ́ra fún ayọ̀ pọ̀rọ́.
Sé ẹ mọ̀ wípé ayọ̀ pọ̀rọ́ ni ó mú àkèré sẹ́ n'ítan.
Ẹ máse fi àwọn dàdá dindín se olóríi yín o, àwọn tí wọn yóò j'oyè àwòdì, ṣùgbọ́n wọn ò ní lè gbé adìẹ, torí wípe ijó ni wón mọ̀ ń jó
tíwọ́n sì má ń jó ní èyìnkùlé òjó ní gbogbo ọjọ́, sé ẹsì m'ọ̀pé; oníjó tí ó bá ti jó mọ níwọ̀n, irú wọn ní ń jópẹ́, èyí tí ò jó mọ níwọ̀n, yóò jótẹ́, yóò fi àte tẹ́di.
Tí a bá yànyín ní olórí, ẹ yá ṣe dáadáa o, torí wípé arúgbó s'oge rí, èkísà náà lo ìgbà tirè, ìgbà a máa gbani; ìgbà a máa pani, ìgbà a máa yẹni, ìgbà asì máa yeni.
Bí èyàn bá wùwà àìdáa lá lọ, kí ó rántí wípé àbọ̀ ń bọ̀ wá bọ̀. Àgbé jẹun yó tán, ó fọ́ akèrègbè, ó ti gbàgbé pé ìgbà òùngbẹ sì ń bọ̀.
Ọ̀rọ̀ sì ń bẹ lẹ́yìn sùgbọ́n. Ìhàhín ni màá ti ṣe ẹnu ní dédé síbí. Ọwọ́ ẹni ni a fihún tún ìwà ara ẹni ṣe. Pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ tí a nà ní pọ̀pá, ẹnití ó bá ta bá kí ó lọ tún bẹ̀ se. Ọlóhun Ọba Àlekè Ọlá, yóò se àánú fún wa. A ò ní b'áwọn ní kílèyí òsán. Bẹ́ẹ̀ni! A ò ní b'àwọn nájà wàràwàrà. Ẹ se àmín, kí ẹ gbé itọ́ àdúrà mì.
Gbogbo ẹtọ wa ni ipamọ. O ko ni ẹtọ lati tun tabi ṣe atẹjade eyikeyi akoonu lati oju opo wẹẹbu yii laisi igbanilaaye kikọ lati ọdọ NEB.

No comments