• Akéèkó OSPOLY Méjì Je Àànfàní Èkó Òfè



    Iseoluwa Adediran


    Idunnu ti subu lu ayo fun akeeko meji kan lati eka ikeko ibanisoro eyiini mass communication ni ile ìwé gbogbonìse ipinle osun ti ilu iree ni bi won se je anfani eko ofe eleyi ti omooba Basiru Olalekan Hassan to je adari ile ifowopamo GT ti ipinle osun ati Oyo se atokun re 


    Awon ti won je anfani oun ni Adedire Dare ti gbogbo eniyan mo si Aremu Akewi àti Emmanuel blessings ti inagije re n je omo ibo Akewi. 


    Anfani yi lo waye ninu ayeye Ojo oroki eleyi ti egbe Awon omo osogbo se ti Awon Akewi meji yii si ke ewi eleyi ti o fi Ewa asa Yoruba han ti o si wu omooba basiru lori ti o si fi da won ni Ola eko ofe.


    Eko ofe oun ni o je eyi ti yio san idasimeji owo ilé ìwé Awon akeeko naa 


    Omooba Basiru Olalekan ni a bi sinu idile modi Oyipi ti o si lo si ile iwe alakobere laro lati odun 1984 si 1990 ati ile iwe girama fakunle comprehensive high school lati odun 1991 si odun 1997 ti o si tesiwaju si ile eko giga ti ipinle Ekiti laarin odun 2000 si 2004 ti o si yege ninu imo nipa isiro 


    Basiru nigbakanri lo ti je akapo egbe omo osogbo ni 2003, ti o si sise pelu ile ifowopamo UBA ni odun 2006 si 2008 ti o si n sise pelu ilé ifowopamo GT lowolowo ti Olorun si fi iyawo ati opolopo omo kée.







    Gbogbo ẹtọ wa ni ipamọ. O ko ni ẹtọ lati tun tabi ṣe atẹjade eyikeyi akoonu lati oju opo wẹẹbu yii laisi igbanilaaye kikọ lati ọdọ NEB. 



    Kan si Olootu;@NAMACOSONLINE

    No comments