ÈTÒ ÌDÌBÒ OSPOLY TALÓ LESÉ: “TI ÌGBÉRAGA KÓ ÌSÈGUN NI TÈMI’’ - HONOURABLE
Dare Adedire, Iseoluwa Adediran
Commrade Azeez Tajudeen Adebayo èyí ti gbogbo ènìyàn mò sí Honourable lati èka ìkéèkó sáyénsì ní ilé ìwé gbogbonìse ti ìpínlè òsun tówà ni ìlú Iree tó tún jé olùdíje sípò ààre egbé akéèkó(S.U.G) ni ó ti fi owo rè soya wípé òun yíò jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò tí yí ò wáyé ní ojóketàdínlógbòn osù keèsán odún tí a wà nínú rè yìí (27th of September 2022)
Èyí ló fojú hànde nínú ìfòròwánilénuwò pèlu olùdíje òún lati owóo egbé oníròyìn ti ilé ìwé gbogbonìse náà èyíinì NEB níbè ni o si se ileri lati se itaniji ètó Awon akéèkó ile iwe ati ètò àbò tí ó péye pèlú awon èròngbà tun tun fún idàgbàsókè awon akéèkó pèlú àlàyé wípé aseyori Awon akéèkó ni o je oun lógún
Bakanna ni ó ro àwon akéèkó lati tu yaya tu yaya jade wa dìbò fun òun àti àwon akegbe òun lapapo fun ominira, alafia ati itesiwaju akéèkó.
Gbogbo ẹtọ wa ni ipamọ. O ko ni ẹtọ lati tun tabi ṣe atẹjade eyikeyi akoonu lati oju opo wẹẹbu yii laisi igbanilaaye kikọ lati ọdọ NEB.

No comments